Hymn 387: To the work! To the work! we are servants of God

Ao sise! ao sise! om- Olorun ni wa

  1. f Ao ṣiṣẹ! ao ṣiṣẹ! ọm-Ọlọrun ni wa,
    Jẹ k’a tẹle ipa ti Oluwa wa tọ̀;
    mp K’a f’imọràn Rẹ̀ sọ agbara wa d’ọtun,
    cr K’a fi gbogbo okun wa ṣiṣẹ t’a o ṣe,
    mf Foriti! foriti!
    cr Ma reti, ma ṣọnà,
    f Titi Oluwa o fi de.

  2. mf Ao ṣiṣẹ! ao ṣiṣẹ! bọ́ awọn t’ebi npa,
    Kó awọn alarẹ̀ lọ ọ’orisun ìye!
    Ninu agbelebu l’awa o ma ṣogo,
    Gbati a ba nkede pe, “Ọfẹ n’Igbala.”
    mf Foriti, &c.

  3. f Ao ṣiṣẹ! ao ṣiṣẹ! gbogbo wa ni yo ṣe,
    Ijọba okunkun at’irọ́ yio fọ́,
    A o si gbe orukọ Jehofa leke,
    N’nu orin iyin wa pe, “Ọfẹ ni’Igbala.”
    mf Foriti, &c.

  4. f Ao ṣiṣẹ! ao ṣiṣẹ! l’agbara Oluwa,
    Agbada at’ ade y’o si jẹ ère wa:
    ‘Gbat’ ile awọn olotọ ba di tiwa,
    ff Gbogbo wa o jọ hó pe, “Ọfẹ n’Igbala.”
    mf Foriti! foriti!
    Ma reti, ma ṣọnà,
    Titi Oluwa o fi de. Amin.