f Ṣiṣẹ tori oru mbọ̀ ! Ṣiṣẹ li owurọ; Ṣiṣẹ nigba ìri nsẹ̀, ṣiṣẹ n’nu ‘tanná; Ṣiṣẹ ki ọsan to pọn, ṣiṣẹ nigb’ òrun nràn; Ṣiṣẹ tori oru mbọ̀ ! ‘gba ṣẹ o pari.
f Ṣiṣẹ tori oru mbọ̀ ! Ṣiṣẹ lọsangangan, F’akoko rere fun ‘ṣẹ, isimi daju. F’ olukuluku ìgba, ni nkan lati pamọ; Ṣiṣẹ tori oru mbọ̀ ! ‘gba ‘ṣẹ o pari.
f Ṣiṣẹ tori oru mbọ̀ ! orùn fẹrẹ̀ wọ̀ na, Ṣiṣẹ ‘gbat’ imọlẹ wà, ọjọ bù lọ tan, Ṣiṣẹ titi de opin, ṣiṣẹ titi d’alẹ, p Ṣiṣẹ gbat’ ilẹ ba nṣu, ‘gba ‘ṣẹ o pari. Amin.