f Gbẹkẹle Ọlọrun rẹ, p K’o ma nṣo! K’o ma nṣo! D’ileri Rẹ̀ mu ṣinṣin, K’o ma nṣo! Màṣe sẹ orùkẹ Rẹ̀, B’o tilẹ mu ẹ̀gan wa; Ma tàn ìhin Rẹ̀ kalẹ̀; Si ma nṣo!
f O ti pè ọ s’iṣẹ Rẹ? cr Sa ma nṣo! Sa ma nṣo! p Oru mbọ̀ wá, mura sin! Sa ma nṣo! Sin n’ifẹ at’ igbagbọ; f Gbẹkẹle agbara Rẹ̀; Fi ori ti de opin; Sa ma nṣo!
f O ti fun ọ ni ‘rugbin? cr Sa ma nṣo! Sa ma nṣo! Ma gbin, ‘wọ o tun kore! Sa ma nṣo! Ma ṣọra, sì ma reti L’ẹnu ọ̀na Oluwa; Y’o dahùn addurà re;
p O ti wipe opin mbọ? cr Sa ma nṣo! Sa ma nṣo! Njẹ fi ẹ̀ru mimọ sin! Sa ma nṣo! Kristi l’ atilẹhìn rẹ, On na si ni onjẹ rẹ, Y’o sìn ọ de ‘nu ogo. Sa ma nṣo!
f Ni akoko diẹ yi: Sa ma nṣo! Sa ma nṣo! Jẹwọ Rẹ̀ ni ọ̀na rẹ: Si ma nṣo! Ka ri ọkan Rẹ̀ n’nu rẹ K’ifẹ Rẹ̀ kẹ ayọ̀ rẹ L’ọjọ aiye rẹ gbogbo, Si ma nṣo! Amin.