- mf Gbà aiye mi, Oluwa,
Mo yà si mimọ fun Ọ;
Gbà gbogbo akoko mi,
Ki nwọn kun fun iyìn Rẹ.
- Gbà ọwọ mi, k’O sì jẹ
Ki nma lo fun ifẹ Rẹ;
Gbà ẹsẹ̀ mi, k’O sì jẹ
Ki nwọn ma sare fun Ọ.
- f Gbà ohùn mi, jẹ ki nma
Kọrin f’Ọba mi titi;
Gbà ète mi, jẹ ki nwọn
Ma jiṣẹ fun Ọ titi.
- mf Gbà wura, fadaka mi
Okan nkì o dá duro;
Gbà ọgbọn mi, k’O sì lo,
Gẹgẹ bi O ba ti fẹ.
- mp Gbà ‘fẹ mi, fi ṣe Tirẹ;
Kì o tun jẹ temi mọ;
Gb’ ọkàn mi, Tirẹ n’ iṣe
cr Ma gunwà nibẹ titi.
- f Gbà ‘fẹran mi, Oluwa,
Mo fi gbogbo rẹ̀ fun Ọ:
Gb’ emi papa; lat’ oni
Ki ‘m’ jẹ Tirẹ titi lai. Amin.