- cr Mo simi le Jesu,
‘Wọ ni mo gbẹkẹle,
p Mo kun fun ẹ̀ṣẹ at’òṣi,
Tani mba tun tọ̀ lọ?
Li okan aiya Rẹ nikan
L’ ọkan arẹ̀ mi simi le.
- mf Iwọ Eni Mimọ!
Baba simi n’nu Rẹ;
Ẹjẹ ètutu ti O ta,
L’o sì mbẹ̀bẹ fun mi:
cr Egùn tan, mo d’alabukún:
Mo simi ninu Baba mi.
- mf Ẹrú ẹ̀ṣẹ ni mi!
‘Wọ l’o da mi n’ ìde;
cr Ọkàn mi sì fẹ lati gbà
Ajaga Rẹ s’ọrùn:
f Ifẹ Rẹ t’o gba aìya mi,
Sọ ṣẹ ati lala d’ ayọ̀.
- ff Opin fẹrẹ de na,
Isimi ọrun mbọ̀;
di Ẹṣẹ at’ irora y’o tan,
Emi o sì de ‘le:
mf Ngo jogun ilẹ ileri,
Ọkàn mi o aimi lailai. Amin.