- mf Iranṣẹ Oluwa!
Ẹ duro nid’ iṣẹ;
Ẹ tọju ọ̀rọ mimọ Rẹ̀,
Ẹ ma ṣọnà Rẹ̀ ṣa.
- Jẹ k’ imọlẹ nyin tàn,
Ẹ tun fitila ṣe;
Ẹ damure gìrigiri,
Orukọ Rẹ̀ l’ ẹ̀ru.
- Ṣọra! l' aṣẹ Jesu,
p B’a ti nsọ, kò jina;
mf B’o ba kuku ti kàn ‘lẹkùn,
Ki e ṣi fun lọgan.
- f Iranṣẹ ‘re l’ẹni
Ti a ba nipo yi;
Ayọ l’on o fi r’Oluwa,
Y’o f’ọla de l’ade.
- mf Kristi tikalarẹ̀
Y’o tẹ́ tabili fun,
cr Y’o gb’ ori iranṣẹ na ga
Larin ẹgbẹ Angẹl. Amin.