- f Ninu oru ibanujẹ
L’ awọn ẹgbẹ erò nrin;
Nwọn nkọrin ‘reti at’ ayọ̀,
Nwọn nlọ silẹ ileri.
- mf Niwaju wa nin’ okunkun,
Ni imọlẹ didan ntàn;
Awọn arakọnrin nṣátẹ́,
Nwọn nrin lọ li aifoyà.
- cr Ọkan ni imọlẹ ọrun,
Ti ntàn s’ara enia Rẹ̀;
Ti nle gbogbo ẹ̀ru jina,
Ti ntan yi ọ̀na wa ka.
- f Ọkan ni ìro àjo wa,
Ọkan ni igbagbọ wa;
cr Ọkan l’ẹni t’ a gbẹkẹle,
Ọkan ni ireti wa.
- ff Ọkan l’orin t’ ẹgbẹrun nkọ,
Bi lati ọkàn kan wa;
di Ọkan n’ijà, ọkan l’ewu,
cr Ọkan ni irìn ọrun.
- f Ọkan ni inu didùn wa,
L’ ebute ainipẹkun;
Nibiti Baba wa ọrun,
Y’o ma jọba titi lai.
- mf Njẹ k’ a ma nṣo, arakọnrin,
T’ awa ti agbelebu:
Ẹ jẹ k’ a rù, k’ a si jiya,
Tit’ a o fi ri ‘simi.
- f Ajinde nla fẹrẹ de na,
Boji fẹrẹ ṣi silẹ̀;
ff Gbogbo okun y’o si tuka,
Gbogbo lala y’o si tán. Amin.