- mf Baba mi, ‘gba mba | nṣako lọ
Kuro l’ṣna Rẹ | l’ aiye yi;
Kọ mi ki nlè wi | bayi pe,
p Ṣe ‘fẹ Tirẹ.
- mp B’ ipin mi l’aiye | ba buru,
Kọ mi ki ngba, ki | nmaṣe kùn!
Ki ngbadura t’ o kọ | mi, wipe,
p Ṣe ‘fẹ Tirẹ.
- mp B’ o kù emi ni|kanṣoṣo,
Ti ará on ọ̀|rẹ́ kò si;
Ni ‘tẹriba ngo | ma wipe,
p Ṣe ‘fẹ Tirẹ.
- mp B’o fẹ gba ohun | ọwọ mi,
Ohun t’ o ṣe ọ̀|wọ́n fun mi;
Ngo fi fun Ọ, ṣe | Tirẹ ni?
p Ṣe ‘fẹ Tirẹ.
- Sa fi Ẹmi Rẹ | tù mi n’nu,
Ki On k’o si ma | ba mi gbe;
Eyi t’o kù, o | d’ọwọ Rẹ,
Ṣe ‘fẹ Tirẹ.
- Tun ‘fẹ mi ṣe lo|jojumọ,
K’ O si mu ohun | na kuro,
Ti kò jẹ k’ emi | le wipe,
Ṣe ‘fẹ Tirẹ.
- ‘Gbat’ ẹ̀mi mi ba | pin l’aiye,
N’ ilu t’ o dara | jù aiye,
L’ em o ma kọrin | na titi.
Ṣe ‘fẹ Tirẹ. Amin.