- mf K’ ọjọ ‘simi yi to tan,
K’a to lọ t’ ara le ‘lẹ
cr A wá wolẹ lẹsẹ Re
di A nkọrin iyin si Ọ
- mf Fun anu ọjọ oni
Fun isimi lọna wa,
f ‘Wo nikan l’a f’ọpẹ fun
Oluwa at’ Ọba wa.
- p Isin wa kò nilari,
Adura wa lù m’ ẹ̀ṣẹ;
Ṣugbọn ‘Wọ l’o nf’ẹ̀ṣẹ jì,
Or’ọfẹ Rẹ to fun wa.
- mf Jẹ k’ ife Rẹ ma tọ́ wa
B’a ti nrìn ‘nà aiye yi;
Nigbat’ àjo wa ba pin,
K’a le simi lọdọ Rẹ.
- f K’ ọjọ ‘simi wọnyi jẹ
Ibẹrẹ ayọ̀ ọrun;
B’a ti nrin àjo wa lo
S’ isimi ti kò l’ opin. Amin.