- f Ọmọ Ọlọrun nlọ s’ogun,
Lati gb’ade Ọba:
Ọpagun Rẹ̀ si nfẹ lẹlẹ,
Tal’ o ṣ’ ọmogun Rẹ̀?
- mp Ẹnit o lè mu ago na,
T’ o lè bori ‘rora,
cr T’o le gbe agbelebu Rẹ̀,
f On ni Ọmogun Rẹ̀.
- mf Martir ikini t’ o kọ kú,
T’o r’ọrun ṣi silẹ̀;
T’o ri Oluwa rẹ̀ loke,
T’ o pe, k’o gbà on là;
- di T’ on ti ‘dariji l’ẹnu,
Ninu ‘rora ikú,
cr O bẹbẹ f’ awọn t’o npa lọ:
f Tani le ṣe bi rẹ?
- ff Ẹgbẹ mimọ; awon wọnni
T’Ẹmi Mimọ bà le;
Awọn akọni mejila,
Ti kò kà iku si:
- f Nwọn f’aiya ràn ida ọta,
Nwọn bá ẹranko jà;
di Nwọn f’ọrùn wọn lelẹ̀ fun ku,
Tani le ṣe bi wọn?
- ff Ẹgbẹ ogun, t’ agbà, t’ ewe,
T’ọkunrin t’obinrin;
Nwọn y’itẹ́ Olugbala ká,
Nwọn wọ aṣọ funfun.
- f Nwọn de oke ọrun giga,
di N’nu ‘ṣẹ́ at’ ipọnju:
p Ọlọrun fun wa l’ agbara
K’ a lè ṣe bi wọn. Amin.