- f Ọmogun Krist, dide,
Mu hamọra nyin wọ̀:
Mu ‘pa t’Ọlọrun fi fun nyin,
Nipa ti Ọmọ Rẹ̀.
- cr Gbe ‘pa Ọlọrun wọ̀,
T’ Oluwa ọmogun;
mp Ẹnit’ o gbẹkẹle Jesu,
O ju aṣẹgun lọ.
- mf Ninu ipa rẹ́ nla,
On ni ki ẹ duro;
‘Tori k’ ẹ ba lè jijà na,
Ẹ di hamọra nyin.
- cr Lọ lat’ ipa de ‘pa,
Ma jà, ma gbadura;
Tẹ agbara okunkun ba,
Ẹ jà, k’ ẹ si sẹgun.
- Lẹhin ohun gbogbo,
Lẹhin gbogbo ija,
K’ ẹ le ṣẹgun n’ipá Kristi,
K’ ẹ si duro ṣinṣin. Amin.