f Duro, duro fun Jesu, Ẹnyin ọm’ogun Krist: Gbe asia Rẹ̀ soke, A kò gbọdọ fẹ kù; cr Lat’ iṣẹgun de ‘ṣẹgun Ni y’o tọ́ ogun Rẹ̀: Tit’ ao ṣẹgun gbogb’ ọta, Ti Krist y’o j’Oluwa.
f Duro, duro fun Jesu; F’eti s’ohùn ipè; Jade lọ s’oju ‘ijà L’oni ọjọ nla Rẹ̀: Ẹnyin akin ti njà fun, Larin ainiye ọta, cr N’nu ewu, ẹ ni ‘gboiya; Ẹ kọjuja s’ọta.
f Duro, duro fun Jesu; Duro l’agbara Rẹ̀; p Ipa enia kò to, Má gbẹkẹle tirẹ: cr Dì ‘hamọra ‘hinrere, Ma ṣọna, ma gbadurà, B’iṣẹ tab’ ewu ba pè, Má ṣe alai de ‘bẹ.
f Duro, duro fun Jesu, di Ija na kì y’o pẹ; p Oni, ariwo ogun, f Ọla, orin ‘ṣẹgun: ff Ẹni t’o ba si ṣẹgun, Y’o gbà ade ìye: Y’o ma ba Ọba Ogo Jọba titi lailai. Amin.