Hymn 376: We’ve no abiding city here:

A ko ni ’bugbe kan nihin

  1. mf A ko ni ‘bugbe kan nihin;
    Eyi bà ẹlẹṣẹ n’nu jẹ;
    cr Kò yẹ̀ k’enia mimọ́ kanu,
    Tori nwọn nfẹ simi t’ọrun.

  2. p A kò ni ‘bugbe kan nihin,
    O buru b’ihin jẹ ‘le wa;
    cr K’ irò yi mu inu wa dùn,
    Awa nwá ilu nla t’o mbẹ̀.

  3. mf A kò ni ‘bugbe kan nihin,
    A nwá ilu nla t’a kò ri;
    Sion ilu Oluwa wa,
    O ntàn imọlẹ titi lai.

  4. mp Iwọ ti nṣe ‘bugbe ifẹ,
    Ibiti ero gbe nsimi;
    Emi ba n’ iyẹ b’ adaba,
    Mba fò sinu rẹ, mba simi.

  5. p Dakẹ ọkàn mi, má binu,
    Akoko Oluwa l’o yẹ;
    cr T’ emi ni lati ṣe ‘fẹ Rẹ̀,
    Tirẹ̀, lati ṣe me l’ogo. Amin.