f Ha! ẹgbẹ mi, ẹ w’asia Bi ti nfẹ lẹlẹ! Ogun Jesu fẹrẹ de na, A fẹrẹ̀ ẹgun! ff “D’ odi mu, emi fẹrẹ̀ de,” Bẹni Jesu nwi, Ràn ‘dahun pada s’ọrun, pe, Awa o dimu.
f Wò ọpọ ogun ti mbọ̀ wa, Eṣu nkó wọn bọ̀; Awọn alagbara nṣubu, p A fẹ damu tan! ff D’odi mu, &c.
Wò asia Jesu ti nfẹ; Gbọ́ ohun ipẹ̀; A o ṣẹgun gbogbo ọta Ni oruko Rẹ̀. ff D’odi mu, &c.
f Ogun ngbona girigiri, Iranwọ wa mbọ̀; Balogun wa mbọ̀ wa tete, Ẹgbẹ, tujuka! ff D’odi mu, &c. Amin.