“Ẹnyin èro, nibo l’ ẹ nlọ, T’ ẹnyin t’ọpa lọwọ nyin? A nrin ajo mimọ́ kan lọ, Nipa aṣẹ Ọba wa. Lori oke on pẹtẹlẹ̀, A nlọ s’afin Ọba rere, A nlọ s’afin Ọba rere, A nlọ s’ilẹ t’o dara A nlọ s’afin Ọba rere, A nlọ s’ilẹ̀ t’o dara.
Ẹnyin erò, ẹ sọ fun ni, Ti ‘reti ti ẹnyin ni? Aṣọ mimọ́, ade ogo, Ni Jesu y’o fi fun wa; Omi ìye l’a o ma mu; A o ba Ọlọrun wa gbe A o ba Ọlọrun wa gbe N’ilẹ̀ mimọ didara; A o ba Ọlọrun wa gbe N’ilẹ̀ mimọ didara.
Ẹ kò bẹ̀ru ọnà t’ ẹ nrìn, Ẹnyin ero kekere? Ọrẹ́ aìri npẹlu wa lọ, Awọn Angẹl yi wa ka, Jesu Kristi l’amọna wa; Y’o ma ṣọ wa, y’o ma tọ wa Y’o ma ṣọ wa, y’o ma tọ wa Ninu ọna ajo wa; Y’o ma ṣọ wa, y’o ma tọ wa Ninu ọna ajo wa.
Ero, a le ba nyin kẹgbẹ, L’ọna ajo s’ilẹ̀ na? Wa ma kalọ, wa ma kalọ, Wa si ẹgbẹ ero wa, Wa, e má ṣe fi wa silẹ̀, Jesu nduro, o nreti wa, Jesu nduro, o nreti wa, N’ilẹ̀ mimọ t’o dara; Jesu nduro, o nreti wa, N’ilẹ̀ mimọ t’o dara. Amin.