f Didan l’ọpagun wa, o ntoka s’ọrun, O nfọnahàn ogun, s’ile wọn ọrun! Lar’n aginju l’a nrin, l’ ayọ̀ l’a ngbadura, Pẹl’ọkàn iṣọkan l’a ‘m’ ọn’ ọrun pọ̀n. Didan l’ọpagun wa, O ntọka s’ọrun, O nfọnahàn ogun, s’ile wọn ọrun.
mf Jesu Oluwa wa, l’ẹsẹ Rẹ ọ̀wọ, Pẹlu ọkàn ayọ̀ l’ọmọ Rẹ pade: p A ti fi Ọ silẹ̀, a si ti ṣako, Tọ́ wa Olugbala si ọnà toro. Didan l’ọpagun wa, &c.
mf Tọ̀ wa l’ọjọ gbogbo, l’ọna t’awa ntọ̀, Mu wa nṣo s’iṣẹgun l’ori ọta wa; di K’ Angẹl Rẹ ṣ’asa wa gb’oju ọrun ṣú p Dariji, si gba wa lakoko iku. Didan l’ọpagun wa, &c.
f K’ a le pẹlu awọn Angẹli loke, Lati jumọ ma yin n’itẹ ifẹ Rẹ: cr ‘Gbat’ajo wa ba pin, isimi y’o de, ff At’ alafia, at’ orin ailopín. Didan l’ọpagun wa, &c. Amin.