- f Jesu, Ọba, ayọ̀ alarẹ̀,
Itunu onirobinujẹ;
Ile alejo, agbara lai,
Ibi isadi, Olugbala.
- f Onifẹ nla, Alafẹhinti,
p Alafia l’ akoko iku;
Ọnà at’ ère onirẹlẹ̀;
‘Wo li emí awọn enia Re.
- Bi mo kọsẹ̀, em’ o kepè Ọ,
Iwọ ti ṣ’ ade onirẹlẹ̀;
Bi mo ṣako, fi ọna hàn mi,
Olugbala at’ Ọrẹ totọ.
- f Ngo jẹwọ ore Rẹ, ngo kọrin
Ibukun, ogo, ìyin si Ọ;
Gbogbo ‘pa mi tit’ aiye y’o jẹ
Tirẹ Olugbala, Ọrẹ́ mi. Amin.