Hymn 371: O Holy Saviour, Friend unseen

Jesu mimo, Ore airi

  1. mp Jesu mimọ, Ọrẹ airi,
    Olurànlọwọ alaini,
    N’nu ayida aiye, kọ́ mi,
    K’emi le rọmọ́ Ọ.

  2. Ki nsa n’ idapọ̀ mimọ yi,
    Gba ohun t’O fẹ ngo kùn bi?
    B’ọkàn mi, b’ẹka ajara,
    Ba sa le rọmọ́ Ọ.

  3. Arẹ ti m’ọkàn mi pipọ,
    Ṣugbọn o wa r’ibi ‘simi;
    Ibukun si de s’ọkàn mi,
    T’ori t’o rọmọ́ Ọ.

  4. mf B’aiye d’ofo mọ mi l’oju,
    B’a gbà ọrẹ at’ ará lọ,
    di Ni suru ati laibọ́hùn
    L’emo o rọmọ́ Ọ.

  5. mp Gbat’ o k’emi nikanṣoṣo
    L’arin idamu aiye yí,
    p Mo gb’Ohùn ifẹ jẹjẹ na
    Wipe, “Sa rọmọ́ Mi.”

  6. cr B’arẹ ba fẹ mu igbagbọ,
    T’ ireti ba si fẹ ṣaki,
    f Kò si ewu fun ọkàn na
    Ti o ba rọmọ́ Ọ.

  7. mf Kò bẹru irumi aiye,
    Nitori ‘Wọ wà nitosi;
    Kì o si gbọ̀n b’iku ba de,
    Tori o rọmọ́ Ọ.

  8. Ire ṣá ni l’ohun gbogbo,
    Wọ agbara at’ asa mi;
    Olugbala, ki y’o si nkan
    Bi mba ti rọmọ́ Ọ. Amin.