Hymn 370: O for a closer walk with God

Emi ‘ba le f’ iwa pele

  1. p Emi ‘ba le f’ ìwa pẹ̀lẹ
    Ba Ọlọrun mi rìn;
    Ki mni imọlẹ ti ntọ́ mi
    Sọdọ Ọdagutan!

  2. mf Ibukun ti mo ni ha dà,
    Gbà mo kọ̀ mọ̀ Jesu?
    p Itura ọkàn na ha da,
    T’ọ̀rọ Kristi fun mi?

  3. Alafia mi nigbana,
    ‘Ranti rẹ̀ ti dùn to!
    Ṣugbọn nwọn ti b’afo silẹ,
    Ti aiye kò le di.

  4. f Pada, Ẹmi Mimọ, pada,
    Ojiṣẹ itunu:
    Mo kọ̀ ẹ̀ṣẹ t’o bi Ọ n’nu,
    T’o lé Ọ lọkan mi.

  5. f Oṣa ti mo fẹ́ rekọja,
    Ohun t’o wu k’o jẹ,
    Ba mi yọ kuro lọkàn mi;
    Ki nle sin ‘Wọ nikan.

  6. Bayi ni ngo b’Ọlọrun rìn,
    p Ara o rọ̀ mi wọ̀!
    ‘Mọlẹ ọrun y’o ma tọ́ mi
    Sọdọ Ọdagutan. Amin.