- f Didun n’ iṣẹ ná, Ọba mi,
Lati mà yin orukọ Rẹ,
Lati ṣe ‘fẹ Rẹ l’owurọ,
Lati sọ ọrọ Rẹ l’alẹ.
- p Didùn l’ ọjọ ‘simi mimọ,
Lala kò si fun mi loni:
Ọkàn mi, mà kọrin iyin
Bi harpu Dafidi didun.
- f Ọkàn mi o yọ̀ n’ Oluwa,
Y’ o yin iṣẹ at’ ọ̀rọ Rẹ̀
Iṣẹ ore Rè ti pọ̀ to!
Ijinlẹ sì ni ìmọ Re.
- mf Emi o yàn ipò ọla
‘Gb’ ore-ofẹ ba wẹ̀ mi nù
cr Ti ayọ̀ pupọ̀ si a mi,
Ayọ̀ mimọ lat’ òke wá.
- f ‘Gbana, ngo ri, ngo gbọ̀, ngo mọ̀
Ohun gbogbo ti mo ti nfẹ;
Lati ṣe ‘fẹ Rẹ titi lai. Amin.