Hymn 369: Why those fears? Behold, 'tis Jesus

Ese d’ eru? wo, Jesu ni

  1. mf Eṣe d’ ẹ̀ru? --- wo, Jesu ni!
    On tikarẹ̀ l’ o ntọkọ́;
    cr Ẹ ti ‘gbokun si afẹfẹ,
    Ti y’o gbe wa la ibú,
    Lọ si ilu
    p ‘Bit’ ọlọfọ̀ ye sọkun.

  2. mf B’a kò mọ ‘bit’ a nlọ gún si,
    Ju b’a ti ngbọhìn rẹ̀ lọ;
    Ṣugb’a kọ̀ ‘hun gbogbo silẹ,
    A tẹle ihin t’a gbọ́;
    cr Pẹlu Jesu,
    A nlà arin ibú lọ.

  3. f A kò bẹ̀ru ìgbi okun;
    A kò sì kà iji si;
    Larin ‘rukerudo, a mọ̀
    P’ Oluwa mbẹ nitosi;
    Okun gba gbọ,
    Iji sá niwaju Rẹ̀.

  4. mf B’ ayọ̀ wa o ti to lọhun,
    Iji ki jà de ibẹ:
    Nibẹ l’ awọn ti nṣọta wa
    Kò le yọ wa lẹnu mọ:
    p Wahala pin
    L’ebute alafia na. Amin.