mf Amọna ọka’n at’Ọgá Awọn èro l’ọna ọrun, Jọ ba wa gbe, ani awa T’a gbẹkẹle Iwọ nikan; cr Iwo nikan l’a f’ọkàn sọ, B’a ti nrìn l’ọna aiye yi.
p Alejo at’ èro l’a jẹ, A mọ̀ p’aiye ki ṣe ‘le wa: cr Wàwa l’a nrìn ‘lẹ òṣi yi, L’aisimi l’a nwa oju Rẹ; f A nyara s’ ilu wa ọrun, Ile wa titilai l’oke.
mp Iwọ ti o rù ẹṣẹ wa, T’ o si fi gbogbo rẹ̀ jì wa; f Nipa Rẹ l’a nlọ si Sion, T’a ndùna ilẹ wa ọrun; Afin Ọba wa ologo, O nsunmọ wa, b’a ti nkọrin.
ff Nipa imisi ifẹ Rẹ, A mu ọna àjo wa pọ̀n; S’ idapọ̀ Ijọ-akọbi, A nrìn lọ si oke ọrun, T’ awa t’ayọ̀ ni ori wa: Lati pade Balogun wa. Amin.