Hymn 367: Onward Christian soldiers, marching as to war

E ma te siwaju, Kristian ologun

  1. f Ẹ ma tẹ̀ siwaju, Kristian ologun,
    Ma tẹjumọ Jesu t’o mbẹ niwaju:
    Kristi Oluwa wa ni Balogun wa,
    Wo! asia Rẹ̀ wà niwaju ogun,
    ff Ẹ ma tẹ̀ siwaju, Kristian ologun,
    Sa tẹjumọ Jesu t’o mbẹ niwaju.

  2. f Ni orukọ Jesu, ogun Eṣu sa,
    Njẹ Kristian ologun, ma nṣo si ‘ṣẹgun;
    cr Ọrun apàdi mì ni hìhó iyin.
    Ará, gbohùn nyin ga, gb’ orin nyin soke
    ff Ẹ ma tẹ̀ siwaju, &c.

  3. f Bi ẹgbẹ́ ogun nlá, n’ Ijọ Ọlọrun,
    di Ará, a nrin l’ọna t’awọn mimọ rin:
    mf A kò yà wa n’ipa, ẹgbẹ kan ni wa,
    Ọkan n’ireti, l’ẹkọ́, ọ̀kan n’ifẹ.
    ff Ẹ ma tẹ̀ siwaju, &c.

  4. mp Itẹ at’ ijọba, wọnyi le parun,
    Ṣugbọn Ijọ Jesu y’o wà titi lai;
    cr Ọrun apadi kò le bor’ Ijọ yi,
    A n’ileri Kristi, eyi kò le yẹ̀.
    ff Ẹ ma tẹ̀ siwaju, &c.

  5. f Ẹ ma ba ni kalọ, ẹnyin enia,
    D’ohun nyin pọ̀ mọ wa, l’orin iṣẹgun;
    cr Ogo, iyìn, ọla, fun Kristi Ọba,
    Eyi ni y’o ma jẹ orin wa titì.
    ff Ẹ ma tẹ̀ siwaju, Kristian ologun,
    Sa tẹjumọ Jesu t’o mbẹ niwaju. Amin.