- f Oluṣagutan y’o pèse,
Y’o fi papa tutu bọ̀ mi;
Ọwọ rẹ̀ y’o mu ‘ranwọ wá,
Oju rẹ̀ y’o sì ma ṣọ mi;
Y’o ma ba mi kiri lọsan,
Loru y’o ma dabòbò mi.
- p Nigbati mo nràre kiri
cr Ninu ìṣina l’ aginju,
O mu mi wá si pẹlẹ,
O fi ẹsẹ̀ mi le ọ̀na;
p Nib’ odò tutu nṣan pẹlẹ,
Larin pápá oko tutu.
- Bi mo tilẹ nrin kọja lọ
p Ni afonifoji iku,
Emi kì o bẹrukẹru,
‘Tori Iwọ wà pẹlu mi;
Ọgọ at’ ọpa Rẹ y’o mu
Mi là ojiji iku já.
- Lẹhìn arẹ ìja lile,
‘Wọ tẹ́ tabili kan fun mi;
f Ire at’ anu ni mo nri,
Ago mi sì nkúnwọsilẹ:
‘Wọ fun mi n’ ireti ọrun,
Ibugbe aiyeraiye mi. Amin.