- f Ngo ṣe foìya ọjọ ibi?
Tabi ki nma bẹru ọta?
Jesu papa ni odu mi.
- B’o ti wù k’ìja gbona to!
K’a máṣe gb´ pe emi nsá;
‘Tori Jesu l’apata mi.
- p Nkò mọ̀ ‘hun t’o le de, nkò mọ̀
Bi nkì y’o ti ṣe wà l’aini;
cr Jesu l’o mọ̀, y’o sì pèse.
- p Bi mo kun f’ẹṣẹ at’òṣi,
cr Mo le sunmọ Itẹ-anu;
Tori Jesu l’ododo mi.
- p B’adurà mi kò ni lari,
cr Sibẹ ‘reti mi ki o yẹ̀;
‘Tori Jesu mbẹbẹ loke.
- f Aiye at’eṣu nde si mi;
ff Ṣugbọn Ọlọrun wà fun mi;
Jesu l’ohun gbogbo fun mi. Amin.