- f A ! alejo at’ ero!
Laiye yi, Laiye yi!
L’ ebi at’ongbẹ l’a wà,
p Irora sì pọ̀ jọjọ,
Laiye yi, Laiye yi.
- p A ! l’òkunkun l’awa nrìn
Laiye yi, Laiye yi!
Oju ẹda gbogbo fọ,
Jesu, jọ ṣe ‘mọlẹ wa
Laiye yi, Laiye yi.
- A ! ẹgbin wà lọkan wa,
Laiye yi, Laiye yi!
mp Irira ọkàn wa pọ̀,
L’ agbo ẹ̀ṣẹ l’a sì wà
Laiye yi, Laiye yi.
- p A ! iku kò jìn si wa
Laiye yi, Laiye yi!
Larin ewu at’ àrun
L’a sì nrin lọjọ gbogbo
Laiye yi, Laiye yi.
- A ! loju ija l’a wà
Laiye yi, Laiye yi!
Eṣu ọta wa n’ipá,
Jesu l’o le gbà wa là,
Laiye yi, Laiye yi.
- p A ! ẹkun, òṣé pọju
Laiye yi, Laiye yi!
Ẹwà rẹ̀, òjijí ni;
Pipe ayọ̀ kò sì sí
Laiye yi, Laiye yi.
- A ! Oluwa pa wa mọ
Laiye yi, Laiye yi!
Yọ wa n’nu buburu rẹ̀;
F’itẹgun Rẹ s’arin wa
Laiye yi, Laiye yi. Amin.