- mf Ọlọrun ẹmi wa, at’ igbàla wa,
‘Mọlẹ òkunkun wa, ‘reti ilẹ wa,
Gbọ́, ki O sì gbà ẹ̀bẹ Ijọ Rẹ yi,
Olodumare.
- mp Wò bi ibinu ti yi Arki Rẹ ka,
Wò b’awọn ọta Rẹ ti nt’ asia wọn,
Bi nwọn si ti njù ọ̀kọ olóro wọn,
‘Wọ le pa wa mọ.
- f ‘Wọ le ṣerànwọ, b’ ìranwọ aiye yẹ̀,
‘Wọ le gbà ni là b’oku ẹṣẹ gbìja;
p Iku at’ Eṣu kò le bor’ Ijọ Rẹ;
F’ alafia fun wa.
- Ràn wa lọwọ tit’ ọta o pẹ̀hìnda,
Fun wọn l’otọ Re, ki a ledariji wọn,
K’a r’ alafia laiye, lehin ìja wa,
Alafia l’ọrun. Amin.