- mf Làrin ewu at’ òṣi,
Kristian, mà tẹsiwaju;
f Rọju duro, jija na,
K’ onjẹ ‘yè mu ọ lòkun,
- f Kristian, mà tẹsiwaju,
cr Wà k’a jẹju kò ọta:
Ẹ o ha bẹ̀ru ibi?
Ṣ’ẹ mọyì Balogun nyin?
- f Jẹ ki ọkàn nyin k’o yọ̀:
Mu ‘hamọra ọrun wọ̀:
cr Jà, ma rò pe ogun npẹ,
Iṣẹgun nyin fẹrẹ de.
- mp Má jẹ k’inu nyin bajẹ,
On fẹ n’ omije nyin nù;
Maṣe jẹ k’ẹ̀ru bà nyin,
B’ aini nyin, l’ agbara nyin.
- mf Njẹ, e ma tẹsiwaju,
cr Ẹ o jù Aṣẹgun lọ;
B’ ọp` ọta dojukọ nyin,
f Kristian, ẹ tẹsiwaju. Amin.