- mf Jesu, ma tọ́ wa,
Tit’ ao fi simi;
mp Bi ọ̀na wa kò tilẹ dàn,
A o tẹle Ọ l’ aifoiya:
f F’ọwọ Rẹ tọ́ wa
S’ ilu Baba wa.
- mp B’ ọ̀na ba lewu,
B’ ọta sunmọ wa,
Ma jẹ k’aigbàgbọ m’ẹ̀ru wa,
Ki gbagbọ on ‘reti mà ye;
f Tor’ arin ọta
L’a nlọ s’ ile wa.
- mp Gbat’ a fẹ́ ‘tùnu
Ninu ‘banujẹ,
Gbat’ idanwo titun ba de,
Oluwa fun wa ni suru;
f F’ ilu nì hàn wa
Ti ẹkún kò si.
- mf Jesu, ma tọ́ wa.
Tit’ ao fi simi:
Amọ̀na ọrun, tọju wa,
Dabobo wa, tù wa ninu,
f Titi ao fi de
Ilu Baba wa. Amin.