- mf Ma tọju wa Baba ọrun,
Larin ‘damú aiye yi;
Pa wa mọ k’o si ma bọ̀ wa,
A kò n’ iranwọ miran;
Ṣugbọn gbogbo ‘bukun l’a ni,
B’ Ọlọrun jẹ Baba wa.
- f Olugbala, dariji wa,
p Iwọ sa m’ ailera wa:
‘Wọ ti rìn aiye ṣaju wa,
‘Wọ ti mọ̀ ‘ṣẹ́ inu rẹ̀;
pp B’ ẹn’ ikanu at’ alarẹ̀,
L’O ti la ‘ ginju yi ja.
- f Ẹmi Ọlọrun, sọkalẹ̀,
F’ ayọ̀ ọrun k’ ọkàn wa;
K’ ifẹ dapọ mọ iyà wa,
At’ adùn ti ki sú ni;
cr B’a ba pese fun wa bayi,
Ki l’ o lè mi ‘simi wa? Amin.