f Ayọ l’ ọjọ ‘simi fun mi,
At’ agogo at’ iwasu’
p Gbat’ a ba mi n’nu ‘banujẹ
mf Awọn l’o nmu inu mi dun.
- Ayọ̀ si ni wakati na
Ti mo lò n’nu agbala Rẹ;
Lati mọ̀ adùn adura
Lati gbà mannà ọ̀rọ Rẹ.
- f Ayọ̀ ni idahùn “Amin”
T’ o gbà gbogbo ile na kan,
Lẹkọkan l’o ndùn t’o nrọlẹ,
O nkọja lọ sọdọ Baba,
- B’ aiye fẹ f’ agbara dè mi
Mọ́ iṣẹ ijọ mẹfa rẹ̀;
f Oluwa, jọ, tù ìde na,
K’ o sọ ọkàn mi d’omnira. Amin.