- mf Ma tọju mi Jehofah nla,
Erò l’aiye oṣì yi;
cr Emi kò n’okun, iwọ ní,
F’ ọw’ agbara di mi mu:
mf Onjẹ ọrun, Onjẹ orun,
Ma bọ mi titi lailai.
- cr Ṣilẹkun isun ogo nì,
Orisun ìmarale;
Jẹ ki imọlẹ Rẹ ọrun
Ṣe amọnà mi jalẹ:
f Olugbala, Olugbala,
Ṣ’ agbara at’ asà mi.
- p ‘Gba mo ba tẹ̀ ẹ̀ba Jordan,
F’ọkàn ẹ̀rù mi balẹ;
cr Iwọ t’ o ti ṣẹgun iku,
Mù mi gunlẹ Kenaan jẹ;
f Orin iyin, Orin iyin
L’emi o fun Ọ titi. Amin.