- mf Kristian, má tì ‘wa ‘simi,
Gbọ b’ Angẹli rẹ ti nwi;
Ni arin ọta l’ o wà;
p Ma ṣọra.
- f Ogun ọrun-apadi,
T’ a kò ri, nko ‘ra wọn jọ;
Nwọn nṣọ ijafara rẹ;
p Ma ṣọra.
- mf Wọ̀ hamọra-ọrun rẹ,
Wọ lọsan ati loru;
Eṣu ba, o ndọdẹ rẹ;
p Ma ṣọra.
- mf Awọn t’ o ṣẹgun ṣaju,
Nwọn nwò wa b’ awa ti njà;
Nwọn nfi ohùn kan wipe,
p Ma ṣọra.
- Gbọ́ b’ Oluwa rẹ ti wi,
Ẹniti iwọ fẹràn;
F’ ọrọ Rẹ̀ si ọkàn rẹ;
p Ma ṣọra.
- Ma ṣọra bi ẹnipe,
Nibẹ ni ‘ṣẹgun rẹ wà;
Gbadura fun ‘ranlọwọ;
p Ma ṣọra. Amin.