- mf Jesu npè wa, lọsàn, loru,
Larin irumi aiye;
cr Lojojumọ l’a ngbohun Rẹ̀
p Wipe,“Kristian, tẹle Mi.”
- mf Awọn Apostili ‘gbaní
Ni odo Galili nì:
Nwọn kọ̀ ile, ọnà, silẹ,
Gbogbo nwọn si ntọ lẹhin.
- Jesu npè wa, kuro ninu
Ohun aiye asan yi;
Larin afẹ aiye, O nwi
p Pe, “Kristian ẹ fẹràn Mi.”
- mf Larin ayọ̀ at’ ẹkun wa,
Larin lala on ‘rọrun;
Tantan l‘o npè l’ohùn rara
p Pe, “Kristian ẹ fẹràn Mi.”
- mf Olugbala nip’ anu Rẹ,
cr Jẹ ki a gbọ́ ipè Rẹ;
F’ eti ‘gbọràn fun gbogbo wa,
K’ a fẹ Ọ ju aiye lọ. Amin.