- mf Iwọ l’Ọna;--- ọdọ Rẹ ni
Awa o ma sa bọ;
Awọn t’o nṣàfẹri Baba,
Yio wa s’ ọdọ Rẹ.
- Iwọ l’ Otọ;--- ọ̀rọ Tirẹ
L’ o lè f’ ọgbọn fun wa;
Iwọ nikan l’ o le kọ wa,
T’ O si lè wẹ ọkàn.
- f Iwọ n’ Iyè; ibojì Rẹ
Fi agbara Rẹ hàn;
Awọn t’o gbeke wọn le Ọ,
Nwọn bọ́ lọwọ ikú.
- Iwọ l’ Ọna, Otọ, Iye,
mf Jẹ k’ a mọ̀ ọ̀na Rẹ;
K’ a mọ̀ otitọ at’iye,
T’ayọ̀ rẹ̀ kò l’opin. Amin.