- mf Ngo sunm’ Ọ, Ọlọrun,
Ngo sunmọ Ọ;
p B’o tilẹ̀ sọ pọonju,
L’ o mu mi wa;
cr Sibẹ, orin mi jẹ,
di Ngo sunm’ Ọ, Ọlọrun,
Ngo sunmọ Ọ.
- mp Ni ọna àjo mi,
B’ilẹ ba ṣú,
Bi okuta si jẹ
Irọri mi;
cr Sibẹ, nin’ alá mi,
di Ngo sunm’ Ọ, Ọlọrun,
Ngo sunmọ Ọ.
- f Nibẹ jẹ ki nr’ ọnà
T’ o lọ s’ọrun;
Gbogb’ ohun t’o fun mi
Nin’ anu Rẹ;
cr Angẹl lati pè mi
di Ngo sunm’ Ọ, Ọlọrun,
Ngo sunmọ Ọ.
- f Njẹ gbati mo ba ji,
Em’ o yin Ọ:
Ngo f’ akete mi ṣe,
Bẹtẹli fun Ọ;
cr Bẹ ninu oṣi mi,
di Ngo sunm’ Ọ, Ọlọrun,
Ngo sunmọ Ọ.
- ff Gba mba fi ayọ̀ lọ
S’ oke ọrun,
T’ o ga ju orùn lọ,
Soke giga:
Orin mi yio jẹ,
di Ngo sunm’ Ọ, Ọlọrun,
mp Ngo sunmọ Ọ.