mp Jesu, mo gb’ agbelebu mi, Ki nle ma tọ̀ Ọ lẹhin; p Otosi at’ ẹni ẹ̀gan, mf ‘Wọ l’ ohun gbogbo fun mi: Bi ìní mi gbogbo ṣegbe, Ti èro mi gbogbo pin; cr Sibẹ ọlọrọ̀ ni mo jẹ! f Temi ni Krist’ at’ Ọrun.
p Ẹda le ma wahala mi, cr Y’o mu mi sunmọ Ọ ni; p Idanwo aiye le ba mi, cr Ọrun o mu ‘simi wá. mf Ibanujẹ kò le ṣe nka B’ ifẹ Rẹ ba wà fun mi; Ayọ̀, kò si le dùn mọ mi, B’ Iwọ kò si ninu rẹ̀.
cr Ọkàn mi, gba igbala rẹ, Bori ẹ̀ṣẹ at’ ẹ̀ru. mf F’ ayọ̀ wà ni ipokipo, Ma ṣiṣẹ, sì ma jìya: mp Rò t’ Ẹmi t’o wà ninu rẹ: At’ ifẹ Baba si Ọ; W’ Olugbala t’o ku fun ọ; cr Ọmọ ọrun, maṣe kùn!
ff Njẹ kọja lat’ ore s’ ogo, N’n’ adurà on igbagbọ; Ọjọ ailopin wà fun Ọ, Baba y’o mu ọ de ‘bẹ. di Iṣẹ rẹ laiye fẹrẹ pin, Ọjọ àjo rẹ mbuṣe, cr Ireti y’o pada s’ayọ̀. f Adura s’orin iyìn. Amin.