mf Ẹwà ‘tanna orọ kùtu, ‘Mọlẹ ọsan gangan, Pipọ́n ọrun li ọjọrọ̀, di Nwọn ti nyara ṣá to! cr A nfẹ ẹnubode ọrun, Ita wura didan: Awa nfẹ Orun Ododo, Ti ki wọ̀ titi lai.
mp B’ ireti giga wa laiye Ti ntete ṣaki to! Abawọn melomelo ni Nb’ agbada Kristian jẹ? cr A nfẹ ọkàn ti ki dẹṣẹ: Ọkàn ti a wẹ̀ mọ́: Ohùn lati yìn Ọba wa, Lọsan-loru titi.
mf Nihin ‘gbagbo on ‘reti mbẹ, Lati tọ́ wa soke; cr Lọhun, pipe alafia Jù b’a ti le fẹ́ lọ: p Nipa ifẹ on ‘rora Rẹ, Nitori iku Rẹ, mf Ma jẹ k’a ṣubu lọna Rẹ, K’a sọ ade wa nù. Amin.