- f Ore-ọfẹ!—b’ o ti dùn to!
T’o gba em’ abòṣi;
cr Mo ti sọnu, o wa mi ri,
O si ṣi mi loju.
- Or’ọfẹ kọ mi ki ‘m’ bẹ̀ru,
O si l’ẹ̀ru mi lọ;
B’ ore-ọfẹ na ti hàn to
Nigba mo kọ gbagbọ!
- Ọpọ ewu at’ idẹkùn
Ni mo ti là kọja;
Or’ọfẹ npa mi mọ d’oni,
Y’o si sìn mi de ‘le.
- Njẹ gbat’ ara at’ ọkàn yẹ̀,
Ti ẹmi ba si pin,
Ngo gb’ ayọ̀ at’ alafia
Loke ọrun lọhun. Amin.