Hymn 350: And dost Thou say, Ask what thou wilt?

Oluwa, Iwo ha wipe

  1. mf Oluwa, Iwọ ha wipe,
    Ki mbere ohun ti mo nfẹ?
    Jọ, jẹ ki mbọ́ lọwọ ẹbi,
    Ati lọw’ẹṣẹ on Eṣu.

  2. cr Jọ, fi ara Rẹ hàn fun mi,
    Si jẹ ki nrù àworan Rẹ,
    Tẹ́ itẹ́ Rẹ si ọkàn mi,
    Si ma nikan jọba nibẹ.

  3. mf Jẹ ki nmọ p’O dariji mi,
    Ki ayọ Rẹ ṣ’agbara mi;
    f Ki nmọ giga, ibú, jijìn
    Ati gigùn ifẹ nla Rẹ.

  4. mf Eyi nikan ni ẹbẹ mi,
    Eyit’ o kù di ọwọ Rẹ:
    Iye, iku, aini, ọrọ̀,
    Kò jẹ nkan, b’O ba jẹ temi. Amin.