Hymn 35: All times and seasons, months and years

Akoko odun at’ osu

  1. f Akoko ọdun at’ oṣu,
    Gbogbo wọn l’Ọlọrun da;
    Ojumọ ni fun ise wa,
    Oru si ni lati sùn.

  2. O si da ọjọ isimi;
    N’nu ‘jọ meje, O mu ‘kan,
    K’ enia ba le r’ aye ṣe
    Ati sìn Ọlọrun wọn.

  3. L’ọjọ mẹfa ni k’a ṣiṣẹ,
    B’o ti yẹ ni ki a ṣe,
    L’ ọjọ keje jẹ k’ a pejọ,
    Ni ile Ọlọrun wa.

  4. L’ ọjọ na yi a ngbadura,
    A nkọrin didun sì I
    A si nyin Ọlọrun l’ ogo,
    T’ o ju ohun gbogbo lọ.

  5. Nisisiyi kọrin iyìn,
    T’Ọlọrun Oluwa wa:
    ff Kọrin didun, kọrin soke,
    Ni yiyin Oluwa wa. Amin