Hymn 349: More holiness give me, more strivings within.

Fun mi n’ iwa mimo; igbona okan

  1. mf Fun mi n’ ìwa mimọ; igbona ọkàn;
    Surù ninu ìya; arò fun ẹ̀ṣẹ;
    Igbagbọ n’nu Jesu; ki nmọ̀ ‘tọju Rẹ̀;
    Ayọ̀ n’nu ìsin Rẹ̀; ẹmi adurà.

  2. f Fun mi l’ọkan ọpẹ; igbẹkẹle Krist’;
    Itara f’ ogo Rẹ̀; ‘reti n’n ọ̀rọ Rẹ̀;
    p Ẹkún fun ìya Rẹ̀; ‘rora f’ọgbẹ Rẹ̀;
    cr Irẹlẹ n’nu ‘danwo; iyìn fun ‘ranwọ.

  3. mf Fun mi n’iwà funfun; fun mi n’iṣẹgun;
    ‘Wẹ abawọn mi nù; fà ‘fẹ mi sọrun;
    Mu mi yẹ ‘jọba Rẹ; ki nwulò fun Ọ;
    Ki nj’ alabukunfun; ki ndabi Jesu. Amin.