- f Alafia ni f’ ọkàn na,
Nibit’ ifẹ gbe wa;
Ifẹ ni o tobi julọ
Ninu gbogbo ẹbùn.
- mf Asan ni gbogbo ‘gbagbọ je,
cr Asan ni ‘bẹ̀ru wa;
Ẹṣẹ y’o bori ọkàn wa,
B’ ifẹ kò si nibẹ.
- Ifẹ nikan ni y’o r’ opin
Igbagbọ on ‘reti;
Nipa rẹ̀ l’a o ma kọrin,
Loke ọrun lọhun. Amin.