- f Wo ! b’ o ti dun to lati ri
Awọn ará t’ o rẹ́;
Ará ti ọkàn wọn s’ ọ̀kan,
L’ ẹgbẹ ide mimọ.
- f ‘Gba iṣàn ‘fẹ t’ọdọ Krist sun,
cr O ṣàn s’ ọkàn gbogbo;
cr Alafia Olodumare
Dabòbò gbogbo rẹ̀.
- O dabi, ororo didùn,
Ni irugbọn Aaron;
Kikàn rẹ̀ m’ aṣọ̀ rẹ̀ run ‘re,
O ṣan s’ agbada rẹ̀.
- p O dara b’ irì owurọ,
cr T’ o nsẹ̀ soke Sion,
Nibi t’ Ọlọrun f’ ogo hàn,
T’ o m’ ore-ọfẹ hàn. Amin.