- f Alabukun ni fun ifẹ,
Ti kì o jẹ k’a yà;
Bi ara wa jina s’ ara,
Ọkàn wa wà l’ọkan.
- mf Da ọpọ Ẹmi s’ ori wa,
Ọna t’ o là l’ a ntọ̀;
Nipa ti Jesu l’ a si nrin,
Iyin Rẹ̀ l’ a nfi hàn.
- Awa ba ma rìn l’ọnà Rẹ̀,
K’ a ma si m’ ohun kan,
K’ a má fẹ ‘hun kan, bikoṣe,
Jesu t’ a pa fun wa.
- f K’ a sunmọ Ọ girigiri,
Ati si ọnà Rẹ;
K’ a ma r’ore gba l’ ọdọ Rẹ,
ff Ẹkún ore-ọfẹ. Amin.