mf Ará, ẹ jẹ k’ a jumọ̀ rìn N’ ifẹ on alafia; A ha lè ma tun berè pe, O tọ k’ a ba f’ija mọ? p Ni irẹpọ, Ni irẹpọ, L’ ayọ, ifẹ, y’o fi pọ̀.
f B’ a ti nrìn lọ sile, jẹ k’ a Ran ‘ra wa lọwọ lọnà; Ọta ká wa nibi gbogbo; S’ọna gbogbo l’ a dẹkùn, mp Iṣẹ wa ni, Iṣẹ wa ni, K’ a ma ran ‘ra wa l’ẹrù.
Nigbat’ a r’ ohun Baba ṣe, T’ o ti fi ji, t’ o nfiji, mp Ara, kò tọ k’ awa k’ o kọ́ Lati ma f’ ija silẹ? K’ a mu kuro, K’ a mu kuro, Ohun ‘ba mu ‘binu wa.
f K’ a gb’ ọmọnikeji wa ga, Ju b’ a ba ti gbe ‘ra wa; K’ a fi keta gbogbo silẹ, K’ ọkàn wa sì kun fun ‘fẹ; mf Yio rọ̀ wa, yio rọ̀ wa, B’a wà n’ irẹpọ l’aiye. Amin.