Hymn 344: Jesus, Lord, we look to Thee;

Jesu, Iwo ni a nwo

  1. mf Jesu, Iwọ ni a nwò,
    K’ a rẹpọ̀ l’ orukọ Rẹ;
    Alade alafia,
    Mú k’ ija tan l’ arin wa.

  2. Nipa ilajà Tirẹ,
    p Mu idugbolu kuro:
    Jẹ k’ a dapọ si ọkan;
    F’ itẹgun Rẹ sarin wa.

  3. f Jẹ k’a wà ni ọkàn kan,
    K’ a ṣe anu at’ orẹ;
    p K’ a tutu l’ erò, l’ọkàn,
    Gẹgẹ bi Oluwa wa.

  4. mf K’ a ṣ’ aniyan ara wa,
    K’ a ma rẹrù ara wa,
    K’ a f’ apẹrẹ fun Ijọ,
    B’ olugbagbọ ti gbe pọ̀.

  5. f K’ a kuro ni ibinu,
    K’ a simi le Ọlọrun;
    K’ a sọ ti iibu ifẹ,
    At’ iwa giga mimọ́.

  6. ff K’ a f’ ayọ̀ kuro laiye,
    Lọ si Ijọ ti ọrun;
    cr K’ a f’ iyẹ Angẹli tò,
    K’ a lè kú b’ ẹni mimọ́. Amin.