- mf “Fẹ ẹnikeji rẹ,”
Aṣẹ Oluwa ni;
O sa f’ ara Rẹ̀ ṣ’ apẹrẹ,
Ni fifẹ t’ O fẹ wa.
- mf “Fẹ ẹnikeji rẹ,”
N’ ire tabi n’ ìja;
O kọ wa pe k’a f’ ọta wa,
K’a f’ ore san ibi.
- mf “Fẹ ẹnikeji rẹ,”
cr Oluwa nke tantan;
O yẹ ki gbogbo wa mura,
K’a f’ ẹnikeji wa.
- mf Fẹ ẹnikeji rẹ,
At’ aladugbo rẹ,
Pẹlu gbogb’ ẹni yi ọ ká,
At’ọta rẹ pẹlu.
- mf K’a f’ẹnikeji wa,
Bi Jesu ti fẹ wa,
cr Jesu sa f’ awọn ọta Rẹ̀.
O si sure fun wọn. Amin.