- mf O fun mi l’ edidi,
‘Gbèse nla ti mo jẹ;
B’o ti fun mi, O sì rẹrin
p Pe, “Maṣe gbagbe mi!”
- mf O fun mi l’ edidi,
O san ìgbèse na;
B’o ti fun mi, O sì rerin
p Wipe, “Ma ranti mi!”
- mf Ngo p’ edidi na mọ́,
B’ igbèse tilẹ tan;
O nsọ ifẹ ẹnit’ o san
Igbese na fun mi.
- f Mo wo, mo sì rẹrin;
p Mo tun wò, mo sọkun;
mf Ẹri ifẹ Rẹ̀ si mi ni,
Ngo tọju rẹ̀ titi.
- Ki tun ọ’ edidi mọ,
Ṣugbọn iranti ni!
f Pe gbogbo igbèse mi, ni
Emmanueli san. Amin.