- f Ki nfẹ Ọ si, Kristi ! ki nfẹ Ọ si:
p Gb’adura ti mo ngba lor’ekun mi,
Eyi ni ẹ̀bẹ mi:-- ki nfẹ Ọ si, Kristi!
f Ki nfẹ Ọ si! ki nfẹ Ọ si !
- Lẹkan, ohun aiye ni mo ntọrọ;
Nisisiyi, ‘Wọ nikan ni mo nwá;
f Eyi l’ adura mi :-- Ki nfẹ Ọ si, Kristi!
Ki nfẹ Ọ si! ki nfẹ Ọ si !
- p Jẹ ki ‘banujẹ e, at’ irora,
Didùn l’ ojiṣẹ Rẹ, at’ iṣẹ wọn.
f ‘Gba nwọn mba mi kọrin, ki nfẹ Ọ si! Kristi!
Ki nfẹ Ọ si! ki nfẹ Ọ si !
- p Njẹ, opin ẹmi mi y’o w’iyìn Rẹ,
Eyi ni y’o jẹ ọrọ̀ kẹhin rè:
f Adurà na o jẹ :-- Ki nfẹ Ọ ọi Kristi !
ff Ki nfẹ Ọ si! ki nfẹ Ọ si ! Amin.